(Composed by late Chief George Ige)
Èsà-Òkè ìlú ọlọ́lá
Ògo àwon baba t’ó bí wa
Orísun ire wa, orísun ayọ̀
Ìbà Ọlọ́run, ìbà Ọba wa
Ọmọ Ẹ̀sà-Òkè ẹ jẹ́ k’á so’wọ́ pọ̀
Ẹ jẹ́ k’á se’ra wa l’ósùsù ọwọ̀
T’ọmọdé t’àgbà , ẹ jẹ́ k’á sẹ́’ra wa
K’á sisẹ́, k’á f’ìfẹ́ han ara wa.
Ẹ̀sà n’ílé, Ẹ̀sà l’óko
Má f’orí mù, má se d’águnlá
K’ọ́jọ́ ọ̀la ọmọ wa le dára
K’áyé yẹ wá ,k’á lè sùn un re
L’ágbára Ọlọ́run àwọn baba wa
Ẹ̀sà-Òkè á gbè wá o.
— Oloye Akin Onifade JP